Russia 2018: Super Eagles ati Poland yoo dije ọlọrẹsọrẹ

Ikọ Super Eagles n ya fọto saaju ifẹsẹwọnsẹ kan Image copyright Nigeria Football federation
Àkọlé àwòrán Orilẹede Naijiria ni orilẹede akọkọ to pegede lati kopa ni Russia 2018 lati ilẹ Afirika

Wọn ti si ibudo igbaradi ikọ agbabọọlu Super Eagles ti orilẹede Nigeria fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu orilẹede Poland ti yoo waye lọjọ aje.

Papa isere ilu Wroclaw ni Naijiria ati Poland yoo ti maa waa ko gẹgẹbii ara igbaradi awọn ikọ agbabọọlu mejeeji fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni osu kẹfa ọdun yii.

Alamojuto fun ikọ agbabọọlu Super eagles fidi rẹ mulẹ wipe ile igbafẹ Radisson Blu lawọn agbabọọlu Super Eagles yoo wọ si lasiko igbaradi ati ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ naa ti yoo waye ni ọjọ ẹti.

Super Eagles fẹyin Angola gbo'lẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper Eagles: Akojọpọ aworan asọ fun ife ẹyẹ agbaye

Saaju ni olukọni ikọ agbabọọlu Super eagles, Gernot Rohr ti fiwe pe awọn agbabọọlu mejidinlọgbọn ti yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti yoo waye naa.

Awọn agbabọọlu naa yoo tun kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ miran pẹlu orilẹede Serbia nilu London nilẹ Gẹẹsi, iyẹn ni ọjọ mẹrin lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu Poland naa.