Igbaradi bẹrẹ ni pẹrẹu fun Super Eagles ni Poland

Ikọ agbabọọlu Super Eagles n ya fọto saaju ifẹsẹwọnsẹ kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbabọọlu mejilelogun lo ti gunlẹ si ibudo igbaradi naa

Agbabọọlu ikọ Super Eagles mejilelogun lo ti gunlẹ si ibudo igbaradai ikọ naa lorilẹede Poland bayii ni imurasilẹ fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti ikọ naa yoo gba pẹlu ikọ agbabọọlu Poland ni ọjọ ẹti.

Awọn adari ikọ super eagles pẹlu awọn agbabọọlu mẹfa ni wọn side ibudo naa ni ọjọ aje sugbọn gbogbo nkan burẹkẹ sii nigba ti awọn agbabọọlu bii Victor Moses, Kelechi Iheanacho, Ahmed Musa, Wilfred Ndidi balẹ si ibudo naa ni ọjọ isẹgun.

Image copyright @thenff
Àkọlé àwòrán Igbaradi ẹẹmeji ọtọọtọ ni awọn agbabọọlu Super eagles yoo se lọjọọru

Lọjọọru ni ireti wa wi pe Ikechukwu Ezenwa ati Daniel Akpeyi yoo darapọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igba meji ọtọọtọ ni awọn agbabọọlu Super eagles to ti gunlẹ si orilẹede Poland se igbadi ni ọjọ isẹgun

Igba meji ọtọọtọ ni awọn agbabọọlu Super eagles to ti gunlẹ si orilẹede Poland se igbadi ni ọjọ isẹgun; eleyi ti wọn yoo tun se pẹlu ni ọjọọru.

Ikọ agbabọọlu Super eagles yoo maa koju Poland gẹgẹbii ara igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye losu kẹfa ọdun 2018 lorilẹede Russia.

Bakannaa ni Super eagles yoo koju Serbia ni ilu London ni ọjọ isẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn osu kẹta.