Ileesẹ ologun Naijiria: A ko gbọ nipa olobo Ikọlu Dapchi

Awọn akẹkọbinrin ileewe girama Dapchi kan joko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn alasẹ ileesẹ ọmọogun Naijiria ni awọn ko gbọ iroyin kankan saaju ikọlu Dapchi

Ileesẹ ologun lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe irọ to jina sootọ ni iroyin kan ti ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International, (AI) gbe sita pe, awọn ta awọn ologun lolobo pe isẹlẹ ikọlu Dapchi yoo waye saaju ki ikọ Boko Haram to sọsẹ ni agbegbe naa.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ isẹgun ni ileesẹ ologun lorilẹede Naijiria ti salaye ọrọ yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ Amnesty International ni wọn fi to awọn ologun leti pe Boko Haram n bọ ni Dapchi

Ileesẹ ologun ni, awọn to mọ isẹ wọn ni'sẹ lo wa ni ẹka ileesẹ oloogun gbogbo lorilẹede Naijiria, kosi si bi eyikeyi ninu wọn se lee gbọ iroyin nipa ohun to jọ ikọlu awọn esinsin-o-kọ'ku Boko haram lai tara sasa.

"Ibeere ti ajọ Amnesty International ko tii dahun daadaa ni wi pe, ewo ninu ileesẹ ologun ati ewo ninu awọn ọọwọ ileesẹ ologun orilẹede Naijiria ni wọn fi iroyin yii to leti wi pe awọn ikọ Boko Haram yoo kọlu ileewe girama ni Dapchi? Kinni nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn pe si?"

Atẹjade ọhun ni, o ti di lemọlemọ ajọ Amnesty International lati maa gbe iroyin 'kobakungbe' jade nipa ileesẹ ologun orilẹede Naijiria ati awọn asiwaju rẹ nigbakugba ti ilẹkun anfani rẹ ba ti si silẹ fun un.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aadọfa akẹkọbinrin ileewe girama ilu Dapchi ni wọn si n wa bayii

Ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International, AI gbe iroyin kan jade ni ọjọ diẹ sẹyin wipe aibikita awọn ologun kun ara ohun to fa bi awọn ikọ Boko Haram se raaye sọsẹ, ti wọn si ji awọn akẹkọbinrin gbe nilu Dapchi.

Ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International, AI ni oun ta ileesẹ ologun orilẹede Naijiria lolobo nipa ikọlu naa sugbọn ti wọn fi gbigbọ se alaigbọ.