Super Eagles: Isoro iwe asẹ igbelu-sisẹ nda Mikel duro

Balogun ikọ Super Eagles, Mikel Obi pẹlu asia orilẹede Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Isoro iwe asẹ igbelu-sisẹ yoo yọ Mikel Obi kuro ninu ikọ Super Eagles to ba n koju Poland

Bi nkan se nlọ bayii, ko daju wi pe Balogun ikọ agbabọọlu Super eagles ti orilẹede Naijiria, Mikel Obi yoo lee kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ to fẹ gba pẹlu Poland lọjọ ẹti.

Mikel yoo maa kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Serbia nilu London.

Gẹgẹbii alamojuto ikọ naa, ọgbẹni Dayo Enebi se sọ, Mikel Obi to n gba bọọlu jẹun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Tianjin Teda lorilẹede China, lee maa darapọ pẹlu wọn nitori pe o nyanju iwe asẹ igbelu-sisẹ rẹ lọwọ lorilẹede naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mikel yoo darapọ mọ awọn akẹẹgbẹ rẹ nilu London fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Serbia

Ọgbẹni Enebi ni, ko si wahala fun awọn ololufẹ ikọ Super Eagles ati balogun ikọ naa ti wọn fẹ ri lori papa nitori pe Mikel Obi yoo darapọ mọ ikọ naa fun ifẹsẹwọnsẹ Super Eagles ati Serbia ti yoo waye ni ọjọ isẹgun to n bọ.

Amọsa o, o fikun pe kii se Mikel Obi nikan ni ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, Oghenekaro Etebo naako ni kopa nitoripe o fara sese nigbati aitete ri iwe asẹ irinna yanju yoo tun yọ Junior Ajayi kuro ninu ikọ naa fun ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igbaradi ikọ Super eagles ti bẹrẹ lorilẹede Poland

Ninu awọn agbabọọlu mejidinlọgbọn ti olukọni ikọ Super Eagles, Gernor Rohr fi iwe pe fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ mejeeji pẹlu Poland ati Serbia, mejilelogun ti de ibudo igbaradi wọn ni Poland, ti wọn si n reti mẹta yooku lọjọru.