Lewandosky: Super Eagles yoo la ọna lati koju Senegal

Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Poland nni, Robert Lewandosky Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Poland yoo lo anfani ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu Super Eagles lati se eto ati koju ikọ agbabọọlu orilẹede Senegal

Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Poland nni, Robert Lewandoski, ti sọrọ lori ohun to faa ti orilẹede Poland fi yan ikọ Super Eagles gẹgẹbii ọkan lara awọn ikọ ti yoo ba dije ọlọrẹsọrẹ rẹ fun igbaradi idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lorilẹede Russia losu kẹfa ọdun 2018.

Ninu ọrọ kan to sọ lori ikanni ayelujara ajọ to n samojuto ere bọọlu lorilẹede Poland, Lewandoski salaye wi pe, nitori awọn ti ikọ agbabọọlu Poland yoo koju ninu ipele akọkọ nibi idije naa lo faa, ti wọn fi yan orilẹede Naijiria fun ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹede Poland yoo koju orilẹede Senegal lati ilẹ Afirika lasiko idije ife ẹyẹ agbaye

Orilẹede Poland yoo koju orilẹede Senegal, Colombia ati Japan ni ipele akọkọ idije ife ẹyẹ agbaye.

Ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu orilẹede Naijiria yoo fun lanfani ati seto ọna ti yoo gba koju ikọ agbabọọlu orilẹede Senegal.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ifẹsẹwọnsẹ meji ni Poland la kalẹ fun igbaradi rẹ losu kẹta ọdun

Lewandosky ni igbagbọ awọn alasẹ ere bọọlu lorilẹede Poland ni wi pe ilana gbigba bọọlu orilẹede Naijiria ati orilẹede Senegal ti wọn yoo koju ko fi bẹẹ yats si ara wọn.

Bakannaa ni poland yoo tun waako pẹlu iks agbabọọlu orilẹede South korea lati fi gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye laarin oun ati orilẹede Japan nibi idije ife ẹyẹ agbabye kan naa.