Hakimi fa jade kuro ni ẹgbẹ Morocco nitori ipalara

Akraf Hakimi ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Hakimi ni ipalara

Akraf Hakimi ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ti yọ kuro ni ẹgbẹ Morocco ti yoo dojukọ Serbia ati Uzbekisitani nitori ipalara.

Ọmọ ọdun mọkandinlogun naa ni ipalara nigba ikọ Atlas Lions nṣe igbaradi ni Turin fun ifẹsẹwọnsẹ ọjọ ẹti pẹlu orilẹede Serbia.

"Achraf Hakimi ni ipalara lakoko ọjọ akọkọ igbaradi ẹgbẹ orilẹ-ede," dokita Atlas Lions, Abidrazak Hifti sọ ninu gbolohun ọrọ kan.

"Aaye rẹ ko tii daju ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ti beere fun pe ki o pada si Madrid."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Hakimi ṣe awọn ifarahan ninu idije mẹrin ti o si jẹ ami ayo kan ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Mali

Hakimi ko tun nii le kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Uzbekistan ni ilẹ Casablanca ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta gẹgẹbi dokita naa ṣe sọ.

Hakimi ṣe awọn ifarahan ninu idije mẹrin ti o si jẹ ami ayo kan ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Mali.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: