Awọn ẹgbẹ ti yoo gba Caf Champions League han nilu Cairo

Awon egbe agbaboolu merindinlogun yoo kopa ninu idije yii Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awon egbe agbaboolu merindinlogun yoo kopa ninu idije yii

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu Wydad Casablanca ti orilẹede Morocco yoo ma wọya'ja pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu AS Port ti orilẹede Togo ninu ipele idije Caf Champions League.

Wọn wa ni isọri kẹta pẹlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu Mamelodi Sundowns ti South Africa ti o gba ife ẹyẹ naa lọdun 2016 ati ẹgbẹ agbabọọlu Horoya ti Guinea.

Pẹlu ifihan yii, o tumọ si pe awọn alagbara ilumọọka ẹgbẹ agbabọọlu to pegede julọ nilẹ Africa ti wọn ti figba kan gba ife ẹyẹ yi ri yoo maa koju ara wọn ninu ifẹswọnsẹ akọkọ ti yoo bere idije Caf Champions League ti saa yii nigbati ẹgbẹ agbabọọlu Casablanca ati Mamelodi Sundowns ba gori papa.

Bakanna ni ẹgbẹ agbabọọlu Al Ahly ti Egypt yoo gbena woju awọn ẹgbẹ agbabọọlu Esperance ti Tunisia ninu isọri kinni.

Image copyright MFM FC/Facebook
Àkọlé àwòrán MFM FC (Nigeria) yoo koju Djoliba (Mali)

Ninu isọri kinni yii naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Kampala City Council ti Uganda ati awọn Township Rollers ti orilẹede Botswana wa.

Ni isọri keji ni ati ri TP Mazembe ti Democratic Republic of Congo, Mouloudia Alger ati Entente Setif lati orilẹede Algeria pẹlu Difaa El Jadidi ti Morocco.

Image copyright @EnyimbaFC
Àkọlé àwòrán Enyimba (Nigeria) yoo wọya ija pẹlu Wits (South Africa)

Isọri kẹrin ri Etoile du Sahel ti Tunisia ti yoo dojuko Primeiro de Agosto ti Angola, Zesco United ti Zambia ati Mbabane Swallows ti Swaziland.

Awọn ifẹsẹwọnsẹ wọnyi yoo maa waye laarin ọjọ krin ati ọjọ kẹfa oṣu karun ọdun.

Awọn isọri ipele idije saa yi:

 • Isọri kinni: Al Ahly (Egypt), Ilu Rollers (Botswana), KCCA (Uganda), Esperance de Tunis (Tunisia)
 • Isọri keji: TP Mazembe (DR Congo), Mouloudia Alger (Algeria), Difaa El Jadidi (Morocco), Entente Setif (Algeria)
 • Isọri kẹta: AS Port ti Togo (Togo), Mamelodi Sundowns (South Africa), Wydad Casablanca (Morocco), Horoya (Guinea)
 • Isọri kẹrin: Zesco United (Zambia), Primeiro de Agosto (Angola), Etoile du Sahel (Tunisia), Mbabane Swallows (Swaziland)

Awọn isọri ipele idije saa yi fun ife ẹyẹ Caf Confederation:

 • Zanaco (Zambia) v Raja Casablanca (Morocco)
 • AS Vita Club (DR Congo) v CS la Mancha (Congo)
 • Saint George (Ethiopia) v Cara Brazzaville (Congo)
 • Al Hilal (Sudan) v Akwa Utd (Nigeria)
 • Gor Mahia (Kenya) v SuperSport Utd (South Africa)
 • UD Songo (Mozambique) v Al Hilal Obied (Sudan)
 • Plateau Utd (Nigeria) v USM Alger (Algeria)
 • Wits (South Africa) v Enyimba (Nigeria)
 • Aduana Stars (Ghana) v Fosa Juniors (Madagascar)
 • Young Africans (Tanzania) v Welayta Dicha (Ethiopia)
 • Generation Foot (Senegal) v Renaissance Berkane (Morocco)
 • Mounana (Gabon) v Al Masry (Egypt)
 • ASEC Mimosas (Ivory Ni etikun) v CR Belouizdad (Algeria)
 • Williamsville (Ivory Coast) v Deportivo Niefang (Equatorial Guinea)
 • MFM FC (Nigeria) v Djoliba (Mali)
 • Rayon Sports (Rwanda) v Costa do Sol (Mozambique).

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: