Super Eagles: So mọ pe ayederu jẹ́ẹ́si lo wọ ?

Agbabọọlu ikọ Super eagles, Alex Iwobi n gba bọọlu ninu jẹẹsi tuntun naa Image copyright @NGSuperEagles
Àkọlé àwòrán Ni orilẹede Russia ni Super eagles yoo ti fi asọ jẹẹsi wọn tuntun dabira

Ikọ agbabọọlu Super eagles ti kede pe awọn jẹẹsi igbabọọlu tuntun ti ajọ to n se amojuto ere bọọlu lorilẹede Naijiria sẹsẹ gba, ko tii si nita fun tita faraalu.

Losu keji ọdun 2018 ni wọn se ifilọlẹ asọ naa, eyiti wọn yoo lo ni idije ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Russia.

Ikọ naa, ninu atẹjade kan to fi sita lori ikanni twitter rẹ lowurọ ọjọ ẹti n,i ayederu ni gbogbo awọn asọ jẹẹsi igbabọọlu ti awọn eeyan kan n ra sọrun kaakiri bayii.

Image copyright @NGSuperEagles
Àkọlé àwòrán Osun keji ọdun 2018 ni wọn se ifilọlẹ jẹẹsi tuntun Super Eagles

Ni ọjọ kẹfa, osu keji ọdun 2018 ni wọn se ifilọlẹ jẹẹsi tuntun yii, eleyi ti ikọ agbabọọlu Super eagles yoo lo lasiko ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye losu kẹfa ni orilẹede Russia.

Ikọ naa ni inu awọn dun pupọ wi pe, awọn eeyan n fi ifẹ han nipa rira awọn asọ jẹẹsi ti wọn ro pe gidi ni, bi o tilẹ jẹ wi pe ayederu lawọn kọlọransi kan n ta fun wọn.