Gernot Rohr: Super Eagles yoo pegede lai si Mikel Obi

Gernot Rohr Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gernot Rohr ni Mikel Obi ni lati yanju iwe asẹ igbelu-sisẹ rẹ ko to yọju si ikọ Super Eagles

Olukọni lere bọọlu fun ikọ Super Eagles, Gernot Rohr ti salaye wi pe ko si sise, ko si aise, ikọ naa gbọdọ gba lati tẹ siwaju pẹlu ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu orilẹede Poland lai si balogun ikọ naa, Mikel Obi.

Mikel Obi to jẹ Balogun ikọ Super Eagles ko ni bawọn peju sibi ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ikọ naa pẹlu Poland.

Gernot Rohr ni lootọ, ikọ naa yoo mọ aisi nile Mikel Obi lara lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa, nitori ifẹsẹwọnsẹ kan soso, ti ikọ naa ti jakulẹ lati igba ti oun ti gba ọpa akoso rẹ, waye lasiko ti mikel Obi ko si nile.

" Igbagbọ mi ni wi p,e nkan yoo s'ẹnu re lọtẹ yii ti Mikel ko ni sile. Lootọ a ni ikọ agbabọọlu to se gbojule, sugbọn a nilo asiwaju.

John Obi Mikel si ni asiwaju ikọ yii ti ẹnikẹni ko lee jiyan rẹ. Ohun ti a si fẹ yẹwo bayii ni lati ri bi awọn agbabọọlu yooku yoo se fakọyọ si, bi balogun wọn ko ba si nile."

O da mi loju pe awọn agbabọọlu yoku yoo fọmọyọ

Gernot Rohr salaye ọrọ yii, nibi ipade to se pẹlu awọn akọroyin lorilẹede Poland ni igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti yoo waye lalẹ ọjọ ẹti.

O ni Mikel Obi ni lati yanju iwe asẹ igbelu-sisẹ rẹ pẹlu afikun wi pe awọn oluranlọwọ wa fun balogun ikọ naa