Ibrahimovic kuro ni Manchester United lẹyin ọdun meji

Zlatan Ibrahimovic Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdun meji ni Ibrahimovic lo ni Manchester United

Gbajugbaja agbabọọlu ikọ Manchester United nni, Zlatan Ibrahimovic ti fi ikọ naa silẹ bayii, lati lọ darapọ mọ ikọ LA Galaxy ni orilẹede Amẹrika.

Awọn alasẹ ikọ Manchester United lo kede ipinya laarin ẹgbẹ agbabọọlu naa ati Ibrahimovic lọjọbọ.

Zlatan Ibrahimovic pẹlu se e lalaye sori ikanni ayelujara twitter rẹ wipe, 'Nkan jankanjankan naa a maa wa sopin, asiko si niyi fun mi lati tẹ siwaju lẹyin saa ere bọọlu meji to larinrin pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester united.'

Ibrahimovic to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ni saa bọọlu ọdun 2016, wa dupẹ lọwọ awọn ololufẹ, alasẹ atawọn osisẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa fun ifẹ ti wọn fi han sii.

Image copyright @ManUtd
Àkọlé àwòrán Awọn alasẹ Man United ni awọn ati Ibrahimovic ko fi ija tuka

Atẹjade kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United fi sita, sọ di mimọ pe, 'adehun alaafia laarin ẹgbẹ agbabọọlu naa ati Ibrahimovic funrarẹ ni wọn fi pinya.'

Lasiko to fi wa pẹlu ikọ Manchester United, Ibrahimovic gba goolu mọkandinlọgbọn sinu awọn, sugbọn isoro ọgbẹ to ni ko jẹ ko lee se bi tatẹyinwa gẹgẹ bo ti se lawọn ikọ to ti gba bọọlu fun ri.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liigi MLS lorilẹede Amẹrika ni Ibrahimovic nlọ

Saaju ko to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United, Ibrahimovic ti gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu to lorukọ bii Ajax lorilẹede Netherlands, Juventus, Inter Milan ati AC Milan lorilẹede Italy pẹlu Barcelona lorilẹede Spain ati PSG lorilẹede France.