Rohr: Oṣu karun ni Super Eagles to n lọ Russia yoo di mimọ

Gernot Rohr, Olukọni ikọ agbabọọlu Super Eagles Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ Super Eagles bẹrẹ igbaradi pẹlu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ni Poland

Olukọni ikọ agbabọọlu Super Eagles ti kede wi pe ni ojọ kẹrinla oṣu karun ni orukọ awọn agbabọọlu ikọ naa ti yoo kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye yoo jade.

Gernot Rohr ṣ'alaye ọrọ yii nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oniroyin ni orilẹede Poland ni igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti yoo waye laṣalẹ ọjọ ẹti.

O ni gbogbo eto lo n to ki ikọ agbabọọlu orilẹede Naijiria lee ṣe aṣeyọri nibi idje ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lorilẹede Russia.

O ni lẹyin ti orukọ naa ba jade tan ni wọn yoo wa gba ipele to pari igbaradi ikọ naa ki wọn to kọri si orilẹede Russia.

Image copyright @NGSuperEagles
Àkọlé àwòrán Oṣu karun ni Super Eagles to n lọ Russia yoo di mimọ

Ninu ọrọ tirẹ, ọkan lara awọn agbabọọlu Super Eagles, Onazi Ogenyi ni ohun gbogbo n lọ ni pẹsẹ ni ibudo igbaradi wọn.

Bakanna lo tun fi da awọn ọmọ orilẹede yii loju wi pe ko lee si wahala ọrọ owo, eleyi to maa n da wahala silẹ fun ọpọlọpọ ikọ agbabọọlu ni Afirika bi wọn ba n lọ fun idije nla bayii ni aarin ikọ Super Eagles o.

Ifẹsẹwọnsẹ orilẹede Naijiria pẹlu Poland yoo waye laago mẹjọ orilẹede Naijiria, ni ọjọ ẹti ni papa iṣere municipal nilu Wroclaw lorilẹede Poland.