Omi n bẹ l'amu fun Super Eagles t'oun tipe wọn na Poland — Rohr

Awọn agbbọọlu Naijiria n yọ nigba ti Victor Moses gba bọọlu si awọn Poland Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Victor Moses lo ba Naijiria jẹ ami ayo kan ninu ifẹsẹwọnsẹ naa

Olukọni ikọ agbabọọlu Super Eagles, Gernot Rhor ti sọ wi pe bi bibori Poland ninu ifẹsẹwọsẹ igbaradi fun idijẹ ife ẹyẹ agbaye ko tumọ si pe Naijiria le gba ife ẹyẹ naa.

Vitor Moses lo ba Naijiria jẹ bọọlu nigba ti orilẹede ọhun na Poland pẹlu ami ayo kan s'odo ninu ifewọnsẹ ti wọn gba l'ọjọ Ẹti.

Alakoso ikọ agbabọọlu orilẹede naa s'apejuwe awọn agbabọọlu Naijiria ọhun gẹgẹ bi ọdọ ti wọn ni awọn oludari laarin wọn.

Ọgbẹni Rohr sọ wipe ti wọn ba tẹsiwaju pẹlu iwa irẹlẹ ati iṣẹ takun-takun lati tun ere bọọlu wọn ṣe, wọn yoo ni ireti to pọ gan.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Rohr sọ wipe Super Eagles kun fun awọn ọdọ

Sugbọn olukọni naa sọ wipe ewe olubori ti Naijiria ja nibi ifẹsẹwọnsẹ rẹ pelu Argentina ati Poland ( ti wọn wa ninu orilẹede mẹwa to mọ bọọlu gba ju lagbaye) ko tumọ si pe Naijiria ti di ọkan lara awọn orilẹede to le gba ife ẹyẹ agbaye nuun.