Ife Àgbáyé 2026: Ọjọ́ 13, Osù Kẹfà la o mọ olùgbàlèjò

Àwòrán Gianni Infantino Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ọdún 2016 ni wọ́n yan Gianni Infantino gẹ́gẹ́ bíí àarẹ Fifa

Àjọ tó ń rí sí erébóòlù lágbàáyé, Fifa ti sọ wí pé ó ku ọ̀la kí Ìdíje Àgbáyé 2018 ó bẹ̀rẹ̀ ni àwọn yóò se ìpolongo orílẹ̀èdè tí yóò gbàlejò Ife Àgbáyé 2026.

Fifa sọ wí pé níbi ìpàdé gbogboògbò tí àwọn yóò se ní Moscow, lorílẹ̀ède Russia ni àwọn yóò ti se ìpolongo náà lọ́jọ́ kẹtàlá, Osù Kẹfà, ọdún yìí.

Fifa, nínú àtẹ̀jáde rẹ̀ sọ wí pé ìdúnàádúrà fún Ife Àgbáyé ti ọdún 2026 náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ àti wí pé, Orílẹ̀èdè Morroco àti Amẹrika pẹ̀lú àjọsèpọ̀ orílẹ̀ède Mexico àti Canada ni ó kù sẹ́nu ìdúnàádúrà fún Ife Àgbáyé náà.

Tí a kò bá gbàgbé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ló tẹ̀lẹ́ ìdúnàádúrà fún Ife Àgbáyé ti ọdún 2018 àti ọdún 2022.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: