Agbabọ́ọ̀lú Man United,Tosin Kehinde, fẹ́ gbá fún Nàíjiríà

Aworan Tosin Kehinde, Ọmọ ẹgbẹ́ agbàbọ́ọ̀lù Manchester United

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

‘Orílẹede Naìjíríà ni mo yan laàyò’

Ọmọ ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù Manchester United, Tosìn Kehìnde ti fi ìpinnu rẹ̀ hàn láti gbá bọ́ọ̀lù fún òrílẹ́èdé Nàíjiríà.

Kehinde tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógùn tó sì ń gbá bọ́ọ̀lù fún àwọn ìkọ̀ Manchester United tí ọjọ́ orí wọn kò ju mẹ́tàlélógún lọ, ní ànfààní láti gbá bọ́ọ̀lù fún òrílẹ́èdè Nàíjiríà àti Ilẹ Gẹ̀ẹ́sì, sùgbọ́n ó ní ọkàn òun rọ̀mọ́ Nàíjiríà.

Agbàbọ́ọ̀lù náà àti àwọn òbí rẹ̀ se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú Àjọ tó ń bójútó ọ̀rọ erébọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá lòrílẹ́èdè Nàíjiríà, NFF ní Ọjọ́ Àiku Ọ̀ṣẹ̀ tí ó kọjá, láti bẹ̀rẹ ìgbésẹ̀ tí yóò fun ní ànfààní láti gbá bọ́ọ̀lù fún Nàíjiríà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Tosin Kehinde ní Alex Iwobi ni àwòkọ́se òun

Agbàbọ́ọ̀lù fún Man United náà sọ wípé Alex Iwobi tó jẹ́ ọmọ Nàíjiríà tó sì ń gbá bọ́ọ̀lù fún Arsenal ni àwòkọ́ṣe òun àti èrò òun láti gbá bọ́ọ̀lù fún òrílẹ́èdè Nàíjiríà ní Ife Ẹ̀ye Àgbáyé ti Russia 2018.