Anthony Joshua ti na Joseph Parker nibi ìdijé ẹ̀ṣẹ

Anthony Joshua against Joseph Parker
Àkọlé àwòrán,

Eleyi ni akoko akọkọ ti Joshua pẹ to bayi ko to naa eeyan nibi ẹṣẹ

Anthony Oluwafẹ́m Joshua ti sọ igbanu ẹyẹ ẹṣẹ WBA, IBF ati WBO di ọkan nigba to na Joseph Parker ni papa iṣere Principality nigboro Cardiff.

Ọmọ Yoruba ọhun to jẹ ọmọ orilẹede Gẹẹsi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), lo ọwọ osi rẹ dara-dara nigba ija ti Parker to jẹ ọmọ orilẹede New Zealand naa ti lo iyawọ rẹ ati amumọra rẹ bo ti yẹ

Sugbọn o da bi ẹni pe igbanu ẹyẹ WBO rẹ yoo pada si idi Joshua nigba to ri awọn ami ayo pataki nibi ẹṣẹ isalẹ agbọn to gba Parker ni ẹsẹ kejọ ati bo ti fi ẹṣẹ ta bi agbọn ni ẹsẹ kewa idije ija naa.

Lẹyin ọrẹyin ni awọn alakoso ija naa ba panupọ pe Anthony Oluwafẹm Joshua lo bori Joseph Parker.

Àkọlé àwòrán,

Joshua ti di ẹlẹṣẹ agbaye - pẹlu igbanu ẹyẹ mẹta , ati ade IBO , igbanu ẹyẹ WBC nikan lo ku fun