Manchester City ti fẹ́ gbá ifé ẹ̀yẹ́ liigi Gẹ̀ẹ́si

Gabriel Jesus scores
Àkọlé àwòrán,

Gabriel Jesus fi ori kan bọ́ọ̀lu ẹlẹkẹsan rẹ̀ wole ninu saa yii

Manchester City yoo gba ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi ti wọn ba na Manchester United ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn yoo gba ni papa isere Etihad lọjọ Abamẹta (Saturday) lẹyin igba ti wọn na Everton.

Akọnimọgba, Pep Guardiola, kọkọ kuna lati bori Everton ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta to gba ni Goodison Park - sugbọn esi yii ko ni tabi-sugbọn ninu lati igba ti Leroy Sané ti gba bọ́ọ̀lu ti David Silva gba si sinu awọn lẹyin iṣẹ́ju mẹrin ti wọn bẹrẹ ere.

Everton ko le ta putu bi Gabriel Jesus ati Raheem Sterling Man City ṣe gba bọọlu meji sinu awọn wọn ki wọn to lọ isimi idaji asiko.

Bọọlu ti Yannick Bolasie ba Everton jẹ ko di Manchester City l'ọwọ ati bori ninu ifẹsẹwọsẹ naa.