West Brom gba íṣẹ́ lọ́wọ́ Pardew

Alan Pardew
Àkọlé àwòrán,

Yíyọ tí wọn yọ Pardew nípò kò ṣẹ̀yìn bí ẹ̀gbẹ́ agbabọ̀ọ̀lu naa ti ṣe wa ni isalẹ̀ atẹ igbéléwọ̀n líìgì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Westbromwich Albion ti yọ olùkọ́ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù rẹ, Alan pardew nipo.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lówúrọ̀ ọjọ́ ajé, àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ni àdéhùn àláfíà ni àwọn àti ọ̀gbẹ́ni Alan Pardew jọ ṣe láti túká lẹ́yìn ìjíròrò.

Bákan náà ni àtẹ̀jáde náà tún ṣàlàyé wí pé ọ̀rọ̀ náà kan amúgbálẹ̀gbẹ́ olùkọ́ni ikọ̀ náà, John Carver.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Olùkọ́ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àgbà lẹ́gbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà, Darren moore ní yóò gba ìṣàkóso ikọ̀ náà fún àsìkò yíí."

Yíyọ tí wọ́n yọ Pardew nípò kò ṣẹ̀yìn bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ti ṣe wà ní ìsàlẹ̀ atẹ igbéléwọ̀n líìgì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.