Juventus v Real Madrid: Ẹ̀san tàbí àfihàn Ronaldo?

Ronaldo ati awọ̀n egbe re ninu idije Champions League

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Madrid lu Juventus lati gba ife ẹ̀yẹ̀ Champions League ni ọ̀dun 2017

Egbe agbabọọlu Real Madrid ati Juventus pade lọdun to kọja nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ aṣekagba ti ọ̀dun 2017 ti Juventus si ṣubu ni abala keji pẹlu ami ayo kan si mẹ̀rin ti Cristiano Ronaldo si jẹ̀ ami ayo meji.

Ṣe ikọ̀ Juventus ṣetan lati gbẹsan nini ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yii?

Pẹ̀lu awọn iriri Giorgio Chiellini ti o sọ pe. "Emi ko ronu nipa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yi bi ẹsan. Nigbati o ba lọ jina ninu idije yii, o pẹ, o ya, o ni lati koju Real Madrid tabi Barcelona.

"Awọn ti o jẹ ẹgbẹ ti o dara julọ ni agbaye ni bayi. Bi o tilẹ jẹ̀ pe, awa naa ni iranti ti o dara ninu awọ̀n ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wa pẹ̀lu wọn."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Juventus yoo gbiyanju lati bori Real Madrid ni Turin lalẹ ọ̀jọ̀ iṣẹ̀gun

Ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mejilelogun ti o ti waye laaarin awọ̀n mejeeji, ikọ̀ Real Madrid fagba han Juventus lẹ̀ẹ̀mẹ̀jọ̀ ti Juventus si bori lẹ̀ẹ̀meje.

Akọ̀nimọ̀ọ̀gba fun Juventus, Massimiliano Allegri wipe "Real Madrid gba ife eye mejila ni Yuroopu. Wọn jẹ ẹgbẹ agbabọ̀ọ̀lu to dangajia pẹ̀lu, ṣugbọn mo ro pe Juventus yoo fakọ̀yọ̀ ninu idije yii paapa julọ̀ ni abala akọ̀kọ̀".

Ẹ̀wẹ̀, Akọ̀nimọ̀ọ̀gba fun Real Madrid, Zinedine Zidane wipe, "awọn ẹ̀gbẹ̀ Juventus ko tii ni ayipada pupọ ni akawe si eyi ti a dije pẹlu ni aṣekagba idije ti saa to kọ̀ja ni Cardiff ṣugbọn ere eyi yoo yatọ patapata nitoripe oṣu mẹwa ti kọja bayi lẹ̀yin ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Real Madrid lu Jventus pelu ami ayo mẹ̀rin si ẹ̀yọ̀ kan

"Saa yi ko lọ̀ gẹ̀gẹ̀bi mo ṣe ro wipe yoo lọ̀ ṣugbọ̀n inu mi dun nitori pe Real Madrid wa ni ipo ti o dara bayi".

Bakanna, ẹ̀gbẹ̀ agbabọ̀ọ̀lu Sevilla yoo maa gbalejo ẹ̀gbẹ̀ agbabọ̀ọ̀lu Bayern Munich ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ keji lalẹ̀ ọ̀jọ̀ iṣẹ̀gun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: