Champions League: Taa ló tún tó bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn Ronaldo?

Peter Crouch
Àkọlé àwòrán,

Peter Crouch fi ọrọ yi da ariyanjiyan silẹ lori Twitter

Esi ti Peter Crouch fọ si goolu ti Cristiano Ronaldo jẹ ninu Champions League ree loju opo Twitter rẹ .

Lotito, ko fẹ si ẹni to wo goolu naa, ti ko se kayeefi lori rẹ nipase bo ti se rẹwa lati wo.

Sugbọn se ẹ ti ri goolu ti Crouch, eyi to mu so iru ọrọ yi?

Àkọlé àwòrán,

Crouch je goolu rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Galatasary ninu idije Champions League

Abi ti Wayne Rooney ?

Àkọlé àwòrán,

Wayne Rooney je goolu to lamilaka ninu ifẹsẹwọnse pẹlu Man City

Ti Ronaldinho nko?

Àkọlé àwòrán,

Ronaldinho kun awọn ti Pweeter Crouch ni wọn sebẹ je iru goolu yi

Gbogbo wọn ni wọn gbiyanju sugbọn lọwọ ti a wa yi, Ronaldo ni awọn ololufe ere boolu, to fi mo aṣọle Juventus, Gianlugi Buffon n kan saara si.

Àkọlé àwòrán,

Gianlugi Buffon gbosuba fun Ronaldo lẹyin ifẹsẹwọnse wọn.

Njẹ kin wa ni ero tiyin?