Man United na Man City mọ'lé ni 2-3

Pogba

Oríṣun àwòrán, Reuters

Manchester United ti gbegidiná jijẹ́ ifẹ ẹ̀yẹ́ liígí Gẹ̀ẹ́si fun Manchester City l'ọjọ́ Àbamẹ́tá (Saturday).

Vincent Kompany lo kọ́kọ́ bá Manchester City jẹ bọ́ọ̀lù lẹ́yín ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dọgbọ̀n si ìgbà tí wọn bẹ̀rẹ̀ ere.

Nigbà to ere di ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni Ilkay Gündogan fi kún fún Manchester United.

Bayíi ni ere náà ṣe jẹ ki wọ́n to lọ ìsimi ìlàjì àsìkọ̀.

Sùgbọn nigbà ti wọn pada wa Paul Pogba ba United jẹ bọ́ọ̀lù mẹjì láàárin ìṣẹ́jú mejì.

Nigbà ti ere di ìṣẹ́jú mọ́kànínlàádọ́rin ni Chris Samalling bá United jẹ bọ́ọ̀lu ẹlẹ́kẹ́tá.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

De gea da birà ninú ìfẹsẹ̀wọsẹ̀ náà