Ìdíje Commonwealth- Ọmọ Nàìjíríà meji yege fun àsekágbá

Ọmọ Nàìjíríà Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adegoke se ipò kíní ni ìpele to kọ́gun si àsekágbá

Ọmọ Nàìjíríà meji, Seye Ogunlewe ati Enoch Adegoke ni wọ́n ti pegedé fun àsekágbá ni ìdíje eré sísá ọlọ́gọ́rùún mítà awọn ọkunrin ninu idije Commonwealth 2018 to n lọ lọ́wọ́ lorilẹede Ghana.

Ogunlewe ni a gbọ́ pe o sepò kẹẹ̀ta ninu abala to kangun si àsekágbá, sugbọn síbẹ̀ to yege fun ìpele asekagba, nigba ti, Adegoke ni tirẹ̀ yege láì kù síbìkan ni ìsọ̀rí tirẹ̀.

Keman Hyman lati orilẹede Cayman Islands lo se ipò kíní nigba ti Akani Simbine lati orilẹ̀ede South Africa se ipò kejì ninu ìsọ̀rí ti Ogunlewe wà.

Ogunlẹwẹ pegede gẹ́gẹ́ bii ọkan lara awọn to kù díẹ̀ sugbọn to se daadaa ni ipò kẹẹ̀ta ní ìsọ̀rí tirẹ̀ ninu ìsọ̀rí mẹ́ta tí wọ́n pín àwọn olùdíje ọ̀ún sí.

Image copyright Getty Images

Sùgbọ́n sa, Ogho-Oghene Egwero to jẹ́ olùdíje lati orilẹede Naijiria bakan naa, ko yege fún ìpele àsekágbá ní tirẹ̀.

Ogunlewe ni yoo mu léènì àkọ́kọ́ ninu ìdíje ọ̀ún ni ọjọ́ ajé to n bọ̀, nigba ti Adegoke yoo mú léènì karùún.

Related Topics