Ìdíje Commonwealth: Australia gbo ewúro sí D’Tigers lójú

Nicholas Kay ti Australia pelu omo Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Australia lu D'Tigers ni 97-55

Lẹyin ijakulẹ ẹlẹ̀ẹ̀kẹta ni ṣisẹ n tẹle ni ọjọ aje, awọn agbabọọlu alafọwọju sapẹrẹ (Basketball) ti orilẹede Naijiria D'Tigers ti kuna nínú ìdíje Commonwealth ti o n l lọwọ nilu Australia.

Ẹgbẹ D'Tigers fidi rẹmi ninu idije mẹta ti wọn ni ninu isọri kinni (Pool A) lai fakọyọ rara ninu wọn.

Eyi tumọsi wipe wọn yoo ṣanwọ pada wale lati ibi idije Gold Coast ni ọdun 2018.

Awọn ẹlẹgbẹ wọn lati orilẹede Australia san bantẹ iya fun wọn pẹlu ami ayo mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn ún si márùndínlọ́gọ́ta (97-55) ninu idije naa lati fi opin si irinajo D'Tigers.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Canada gbo ewuro si D'Tigers loju pẹlu 82-67

Bi o tilẹ jẹ wipe arakunrin ọmọ orilẹede Naijiria Ikechukwu Diogu gbiyanju ti o si jẹ ami ti o pọju lọ ninu idije naa pẹlu ami mọkandinlogun (19), ṣugbọn ẹpa ko boro mo fun ẹgbẹ D'Tigers.

Wọn padanu idije akọkọ wọn pẹlu ami àádọ́fà si márùndínláàdọ́rin (110-65), lẹyin na ni orilẹede Canada gbo ewuro si wọn loju pẹlu ami méjílélọ́gọ́rin si mẹ́tàdínláàdọ́rin (82-67).

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: