Ìdíje Commonwealth: Àkàndá ẹ̀dá Nàíjíríà mókè nínú irin gbígbé

Esther Oyema Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Esther Oyema fi àmì tuntun lélẹ̀ ni eré ìdárayá irin gbígbé

Esther Oyema, to ń ṣojú orílẹ̀èdè Nàìjíríà níbi ìdíje Commonwealth tó ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀èdè Australia, ti gba àmì ẹ̀yẹ góòlù níbi eré ìdárayá irin gbígbé (para powerlifting) fún àwọn obìnrin àkàndá.

Esther Oyema fi àmì tuntun lélẹ̀ ni eré ìdárayá irin gbígbé fún àwọn obìrin àkàndá, nígbà tó gba àmì 141.6, láti borí akẹgbẹ́ rẹ̀, Lucy Ejike.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àmì ẹ̀yẹ góòlù ti Esther Oyema gbà yíi, ni yóò sọ iye àmì gọ́ọ̀lù tí orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti gbà níbi ìdíje naa di méjì.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àmì gọ́ọ̀lù tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gbà níbi ìdíje naa di méjì

Roland Ezuruike pẹ̀lú gba góòlù ninu eré ìdárayá irin gbígbé para powerlifting kannáà fún àwọn ọkùnrin.

Ní ilẹ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun tó mọ́ yìí, ipò kẹwàá ni Nàìjíríà wà lórí àtẹ ìgbéléwọ̀n àwọn orílẹ̀-èdè tó ń kópa nínú ìdíje Commonwealth tó ń lọ lọ́wọ́.

Ipò Orílẹ̀-èdè Góòlù Fàdákà Bààbà
Ikini Australia Mọkanlelogoji (41) Mẹrinlelọgbọn (34) Mẹrinlelọ̀gbọ̀n (34)
Ikeji England Mẹtalelogun (23) merindinlọ̀gbọ̀n (26) Ogun (20)
Ikẹta India Mọkanla (11) Mẹrin (4) Marun (5)
Ikẹrin New Zealand Mẹjọ (8) Mẹwa (10) Meje (7)
Ikaarun South Africa Mẹjọ (8) Marun (5) Marun (5)
Ikẹfa Canada Meje (7) Mẹtadinlogun (17) Mẹtala (13)
Ikeje Wales Meje (7) Meje (7) Mẹrin (4)
Ikẹjọ Scotland Mẹfa (6) Mẹsan (9) Mejila (12)
Ikẹsan Nàìjíríà Mẹrin (4) Mẹrin (4) odo (0)
Ikẹwaa Cyprus Mẹrin (4) odo (0) Meji (2)

Àmì ẹ̀yẹ góòlù méjì àti fàdákà mẹ́rin ni Naijiria ṣi ni nibi idije naa.

Orílẹ̀-èdè Australia ló ń léwájú nínú ìdíje náà pèlú góòlù ogójì, fàdákà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti bààbà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Roland Ezuruike pẹ̀lú gba góòlù ninu eré ìdárayá irin gbígbé