Champions League: Sé Man City leè borí Liverpool

Aworan Pep Guardiola Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọgbọn wo ni Pep Guardiola gbọdo lda bayi lati fi bori Liverpool?

Nje Man City le yi nnkan pada bii nigba ti wọn ba koju Liverpool lale oni?

Ibeere ree ti ọpọ ololufẹ ere bọọlu nbeere, paapa ju l,o awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Man City.

Ipenija to wa ni iwaju akọni ẹgbẹ Man City, Pep Guardiola ati ikọ rẹ ko kere rara .

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ami ayo mẹta ni Liverpool ti fi sagba wọn nigba ti won kọkọ pade ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele kinni abala komẹsẹoyo idije Champions League.

Ki wọn to le pegede, ami ayo mẹrin ni wọn gbọdo je, ti Liverpool ko si gbọdo je pada.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mohammed Salah, atamatese Liverpool le je adinagboogun fun Man City

Ninu ipade to waye tele

  • Tohun ti bi ipade yi ti se je akọkọ awọn mejeji ni Yuroopu, wọn ti pade ri nigba méjídínlọ́gọ́sàn (178) ni Liigi ilẹ Gẹẹsi.
  • Liverpool fagba han Man City nigba mẹ́tàdínláàdọ́rùn (87), ti Man City si jawe olubori ni igba márùndínláàdọ́ta.
  • Won gba ọmi ayo mẹ́rìndínláàdọ́ta.
  • Ni saa liigi tọdun yi, City jẹ ami ayo to pọju ninu ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu Man United pẹlu ami ayo marun si odo 5-0, ni osu kẹsan 2017.
  • Liverpool yi nnkan pada ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Man City to waye lọjọ kẹrinla osu kinni.
  • Ami ayo mẹrin si mẹta ni wọn fi ta iko Pep Guardiola yọ.
  • Eyi ni ipade ninu idije alabala meji, ẹlẹkẹẹta iru re, fawọn ẹgbẹ agbabọọlu naa.
  • Liverpool lo pegede ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ meji to ti waye saaju ninu abala to kangun si asekagba ife ẹyẹ English League Cup.