Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Liverpool àti Man City: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé

Aworan Mohammed Salah Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹkun ọkọ oke. Salah se atọna ijakule Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn.

Ina eṣi ti mu Man City lẹẹmeji : Liverpool ti ja wọn kuro ninu idije Champions League pelu ami ayo 5-1 lapapo.

Dipo awọn ikọ Pep Guardiola, awọn ọmọ Jurgen Klopp ni yoo soju ile Gẹẹsi ninu abala to kangun si asekagba Champions league.

Labala kini ati ikeji ifẹsẹwọnsẹ wọn, Sallah tan bi osupa sugbọn awọn iselẹ manigbagbe kan waye ninu ifẹsẹwọnsẹ abala keji.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Goolu Leroy Sane naa se bi ẹni pe o tọ sugbọn alamojuto fagile.

Ifagile goolu Sane

Bi alamojuto ti se wogi le goolu Leroy Sane je iselẹ manigbagbe kan pataki ninu ifesewonse naa.

Kani pe o gba goolu naa wole ni, Man City ko ba ni ayo meji ni abala akoko.

Eyi si le se okunfa ki won jawe olu bori ninu ifesewonse naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Raheem Sterling damu oju ile Liverpool sugbọn ko ja si goolu fun

Igbesubu Raheem Sterling

Awọn alatileyin Man City yoo ma jaran bi alamojuto ti se kaju kuro lara igbesubu Raheem Sterling lemeji.

Ki ba se pe o gba ọkan wole ninu wọn ni ,agaga igbesubu ẹlẹkeji ,boya ọto ni nnkan ti a ba ma wi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Inu Pep Guardiola ko dun si awọn igbese alamojuto ti o si fi ẹdun ọkan re han

Ilejade Pep

O le jọ wi pe goolu Salah sokunfa ijakule Man City sugbọn awọn kan ni bi alamojuto ti se le Pep Guardiola jade gaan lo se ọpọ akoba fun awọn agbabọọlu re.

Muse muse wọn ko gba muse to pẹlu aisinle olukọni wọn ti o si fara han bi wọn ti se gba boolu ni saa keji.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Goolu elekeji ti Firminho gba wole da Man City lẹyin patapata

Firminho pari ijo

Goolu ẹlẹkẹsan rẹ ninu idije Champions League ti Firminho gba wole ninu ifẹsẹwọnsẹ abala keji pẹlu Man City lo pari ẹjọ.

Atamatase naa fi ajulo han Man City pẹlu bi ko se jafira lati gba boolu wo inu awọn Man City.