Ndidi: Jẹẹsí Nàíjíríà ní Russia‘18 jẹ́ ìwúrí fún mi

Wilfred Ndidi ọmọ agbbábọ́ọ̀lù Leicester City Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbábọ́ọ̀lù Leicester City náà sàlàyé pe wíwọ aṣọ orílèdè Nàìjíríà jẹ́ ohun ìwúrí fún òun

Agbábọ́ọ̀lù ààrin ọmọ Nàìjíríà Wilfred Ndidi, ń fojú sun wíwọ aṣọ orílèdè Nàìjíríà níbi ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti ọdún 2018 ní orílèdè Russia

Ndidi kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó mú orílèdè Nàìjíríà fákọyọ láàárín àwọn akópa tó kù

Ndidi tó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ Leicester City ṣe gudugudu méjé yàyà mẹfà níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí o mú ikọ̀ Super Eagles yẹ fún ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tí yóò wáyé lọ́dún yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ndidi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ tó nírètí láti sojú orílèdè Nàìjíríà ní ilẹ̀ Russia

'' Ó Jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi pé ń sojú fún orílèdè mi níbi ife ẹ̀yẹ àgbáyé, ó jọmi lójú púpọ̀, mi ò tilẹ̀ tíì ròó lọ títí sùgbọ́n mo gbàgbbọ́ pé gbogbo rẹ̀ yóò di òkodoro nígbà tí a bá dé Russia.