Ìdíje CAF: USM Algiers já ìràwọ̀ Plateau Utd

Aworan Oussama Darfalou Image copyright TWITTER/ USM ALGER
Àkọlé àwòrán Oussama Darfalou je ayo mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ naa

Ẹgbẹ agbabọọlu USM Algiers lorilẹede Algeria, ti yọwọ Plateau United ti Naijiria kuro lawo ninu idije Caf Confederations Cup.

Ami ayo mẹrin sodo ni wọn fi sagba wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye ni Stade 5 Juillet Algiers .

Saaju, wọn ti gba ami ayo meji si ọkan nile Plateau United.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lapapo, ami ayo marun si meji ni USM fi tẹsiwaju si abala to kan.

Image copyright TWITTER/USM ALGERS
Àkọlé àwòrán Epa o boro mọ fun Plateau United bi USM se rojo goolu sile wọn

Oussama Darlafou to gba ami ayo kan soso, ti USM je wọle, ninu abala akoko ifẹsẹwọnsẹ wọn ni Naijiria, lo fori je ayo akoko, ni nkan bi iseju mẹrin si igba ti abala kinni yoo fi pari.

Oun kan yi naa lo je ayo keji ati ikẹta, ki Mokhtar Benkhermassa to fi ikẹrin lee ni ipari ifẹsẹwọnsẹ naa.

O ku Enyimba,MFM ati Akwa

Ninu awọn ifesewonse miran ti yoo waye loni, eyi to kan awọn ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, MFM ti setan lati na tan pẹlu Djoliba AC ni Bamako Mali.

Image copyright PIUS UTOMI EKPEI/GETTY
Àkọlé àwòrán Awọn ololufe Eyinmba ni ireti pe ẹgbẹ awọn yoo bori Bidvest Wits

Ami ayo kan sodo ni Djoliba na wọn, nigba ti wọn pade ni abala kinni ifẹsẹwọnsẹ wọn ni Eko.

Al Hilal ti gbọn ewuro ami ayo meji sodo si Enyimba loju saaju.

Enyimba, to ti gba ami ayo kookan pẹlu Bidvest Wits lorileede South Africa yoo gbiyanju lati tẹsiwaju nigba ti awọn mejeji ba pade ni Aba.

Akwa United yoo gbalejo Al Hilal ti orileede Sudan lẹyin ti Al Hilal ti gbọn ewuro ami ayo meji sodo si wọn loju saaju.