Àwọn ọ̀dọ́ kojú ààrẹ́ Buhari

Ààrẹ Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọ̀dọ́ kojú ààrẹ́ Buhari

Ariwo awuyewuye to n lọ kaakiri ori ẹrọ ayelujara bayii nipa ọrọ kan ti wọn ni Aarẹ Buhari sọ ni ilu London pe awọn ọdọ orilẹede Naijiria ko kawe wọn o si fẹ iṣẹ ṣe ko tii jẹ rodo lọ mumi o.

Koda, awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaa julọ awọn ọdọ, ti n lo anfani naa lati ṣalaye akitiyan ati iyanju ti wọn n gba lati gbọ jijẹ mimu ara wọn.

Diẹ ninu wọn niyii.

"Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìsègùn òyinbo ni mi, mo wa nipele tó parí mo n ta ẹ̀sọ́ ọwọ́ ati t'ọrun mo si tun n se owo sise eto igbeyawo atawọn inawo mii. @Buhari, emi kii se ọlẹ".

"Ọ̀dọ́ orilẹede naijiria ni mi ti mo si gba oye kilasi akọkọ, First class ninu imọ nipa kokoro arun kekeeke, Microbiology mo n se mo si n ta ogi... Dajudaju mi o y'ọlẹ".

"Ọmọ Naijiria ni mi, agbẹjọro ni mi, àgbẹ̀ ni mi, emi kii se ọlẹ".

"Mo jẹ́ ọkan lara awọn ọdọ Naijiria to nsisẹ wọ oru ọganjọ lati se asọ oke lọsọọ fun awọn onibara mi lowo ti ko gun ni lapa mo si n ta a kaakiri Naijiria..."

Àwọn ọ̀dọ́ Naijiria tun gbe aworan awọn agbalagba asofin Naijiria kọọkan nibi ti wọn ti nsun lẹnu isẹ́ jade lati beere wipe taa wa lọlẹ gan?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: