Chelsea na Burnley ni 2-1 mọ̀lé nínú ìdíje Premier league

Aworan Victor Moses Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Moses dawọ idunu pẹlu awọn akẹgbẹ re lẹyin to je goolu keji ninu ifẹ̀sẹ̀wònse wọn.

Victor Moses tàn bí òṣùpá nígbà tí Chelsea na Burnley mọ́lé pẹ̀lú àmìn ayò méjì ṣọ́kan nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ líìgì Premiership.

Ilakaka Moses ṣokunfa bí Kevin Long ṣe gbà bóòlù wọnú ile Burnley ní abala kíni ifẹ̀sẹ̀wònse náà.

Ni abala kejì, Burnley da ayo kan padà sùgbón kò pé lẹyìn tí wọn jẹ ni Victor Moses gba ayo kejì wọlé fún àwon àlejò náà.

Pẹlu abajade ifẹ̀sẹ̀wọnsẹ yii, Chelsea ti mu adiku ba alafo to wa laarin won ati Tottenham ku si ami maarun.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu merin toi ba pegede ninu liigi ni yooo lanfaani ati kopa ninu idije Champiosn League lọdun to'n bọ.

Ninu ifẹ̀sẹ̀wònse míràn, Leicester àti Southampton gba omi.