Ilé isẹ́ ìgbóhùsáfẹ́fẹ́ SSBC dá ètò Ilé isẹ́ BBC dúró

Olùgbọ́ ètò BBC
Àkọlé àwòrán South Sudan ti ilé isẹ́ BBC pa torí àìsanwó

Ilé isẹ́ ìgbóhùsáfẹ́fẹ́ BBC sọ wípé ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó lawọn tó ńgbọ́ wọn ní orílẹ̀èdè South Sudan.

Àwọn alásẹ South Sudan ti ti ilé isẹ́ rẹ́díò BBC tó wà ní olú ìlú orílẹ̀èdè náà, Juba àti ní Wau pa.

Mòlúmọ̀ká òsìsẹ́ ilé isẹ́ ìgbóhùsáfẹ́fẹ́ South Sudan iyẹn SSBC, Magok Chilim sọ wípé ilé isẹ́ BBC kọ̀ láti san àwọn owó tí wọ́n njẹ ẹ́ lẹ́yìn tí ó tún rán ilé isẹ́ náà létí nínú osù kínní ọdún.

Ó ní se ni òun yóò wọ́ ilé isẹ́ BBC lọ sílé ẹjọ́ bí wọn ò bá san gbèsè owó tí wọ́n jẹ ẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú ọ̀rọ̀ kan, BBC ní àwọn kábamọ̀ pé ilé isẹ́ SSBC pinu làti dáwọ́ gbígbóhùnsáfẹ́fẹ́ àwọn ètò BBC fún olùgbọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó lórílẹ̀èdè South Sudan dúró.

Ó fi kún un wípé ilé isẹ́ náà ti nsisẹ́ takuntakun láti mú kí ọ̀rọ̀ wọ̀ padà pẹ̀lú ilé isẹ́ SSBC láti lè dá àwọn ètò wọn padà sórí afẹ́fẹ́.