Man United bọ́ si ìpele àsekágbá ninu ìdíje FA

Manchester United Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester United fi ìdùnú wọn hàn

Egbẹ́ agbábọ́ọ́lù Manchester United ti bọ́ sí ìpele àsekágbá ninu ìdíje FA lẹ́yìn ti wọ́n na ẹgbẹ́ agbabọọlu Tottenham ni àmì ayò meji si ẹyọkan.

Alexis Sanchez lo fi góòlù alákọ̀ọ́kọ́ sọwọ sinu ile Tottenham, ki Ander Herrera naa tó gbá ẹlẹ́ẹ̀kejì wọle, lẹ́yìn tí Dele Alli ti kọ́kọ́ fi góòlù kan kí Man United káàbọ̀ sori pápá ni Wembly.

Ìsẹ́jú kọkànlá ni góòlù àkọ́kọ́ ninu ìdíje ọ̀ún wọle sinu àwọ̀n Manchester United lati ọ̀dọ̀ Tottenham, sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nigba ti Sanchez yí ìpinu Tottenham pada ni ìsẹ́jú kẹrìnlelógún, ti Herrera sì fọba lée ni abala kejì ìdíje.

Ìdije yii ko ba jẹ́ anfaani fun Mauricio Pochettino lati yi ìtàn ọdún mẹ́rin rẹ̀ pada ninu ẹgbẹ́ agbabọọlu Tottenham Hotspur, sùgbọ́n ti Man United kò jẹ́ ki àlá dòun fun akọ́nimọ̀ọ́gbá ọ̀ún lati gba ife àkọ́kọ́ fun Tottenham.