Líìgì ilẹ Gẹẹsì: Salah ni agbábọọlù tó pegedé jùlọ

Mohammed Salah Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Salah gbẹyẹ mọ agbábọọlù márùn ún lọ́wọ́

Wọn ti kéde agbábọọlù Liverpool àti ọmọ orílẹèdè Egypt, Mohammed Salah, gẹgẹ bíi agbábọọlù tó pegede jùlọ, ní sáà ìdíje líìgì premiership ilẹ Gẹẹsì fún ọdún 2017 si 2018.

Salah gbẹyẹ mọ Kevin de Bruyne, ( Manchester City), Harry Kane (Tottenham), Leroy Sane (Manchester City), David Silva (Manchester city) àti David de Gea (Manchester United) lọwọ, láti gba àmì ẹyẹ PFA náà.

Bakannaa ni wọn fún Sane ni àmì ẹyẹ ọjẹ wẹwẹ agbabọọlu to pegede julọ, ni liigi naa fun ọdun 2017-2018.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Salah ni ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kejì tí yóò gba àmì ẹ̀yẹ yìí, lẹ́yìn Riyad Mahrez

"Iyi nla lo jẹ fun mi paapaa julọ bo ṣe jẹ pe àwọn agbabọọlu akẹẹgbẹ mi lo di ibo yan mi.

Mi o raaye to bi o ṣe yẹ nigba ti mo wa pẹlu ikọ Chelsea. Amọ sa, ipadabọ mi jẹ pẹlu ọkan ọtọ"

Olukọni ikọ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp, ni inu oun dun fun anfaani lati jẹ olukọni fun Salah.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Mi o raaye to bi o ṣe yẹ nigba ti mo wa pẹlu ikọ Chelsea'

Awọn agbabọọlu ni wọn maa n dibo lati yan ẹni ti wọn ba wo pe, o fakọyọ julọ laarin wọn.

Salah ni ọmọ ilẹ Afirika keji ti yoo gba ami ẹyẹ yii, lẹyin ti Riyad Mahrez ti gba a, ni saa bọọlu 2015 si 2016, pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Leicester city.

Related Topics