Ìdíje Champions league: Salah dá iná ayò sára Roma

Mohammed Salah ka ọwọ soke Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ń pè fún gbígbé ádé agbábọ́ọ̀lù tó mọ̀ọ gbá jùlọ lágbáyé lé Salah lórí

Mohammed Salah, agbábọ́ọ̀lù Liverpool tún jẹ́wọ́ ọmọ ọkọ ní àṣalẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun, nígbà tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liverpool na Roma pẹ̀lù àmì ayò márùn ún sí méjì.

Ifẹsẹwọnsẹ naa ni abala akọkọ ipele to kangun si aṣekagba ninu idije Champions league ilẹ Yuroopu, fun saa bọọlu afẹsẹgba ọdun 2017 si 2018.

Meji ninu ayo marun ti Liverpool gba wọ inu awọn Roma, lo wa lati ẹsẹ Salah.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iye goolu ti Salah ti wọnu awọn ni saa ere bọọlu yii ti di mẹtalelogoji

Ni bayii, iye goolu ti Salah ti wọnu awọn ni saa ere bọọlu yii ti di mẹtalelogoji.

Iṣẹju karundinlogoji ifẹsẹwọnsẹ naa ni Salah gba ayo akọkọ wọle ko to gba ikeji wọle ni iṣẹju karundinlaadọta.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Amọṣa ẹgbẹ agbabọọlu Roma ja fitafita lati da meji pada lati ẹsẹ First Edin Dzeko ati Diego Perotti

Sadio Mané gba ayo tirẹ wọle ni iṣẹju kẹrindinlọgọta, ki Firmino to gba meji wọle sii.

Amọṣa ẹgbẹ agbabọọlu Roma ja fitafita lati da meji pada lati ẹsẹ First Edin Dzeko ati Diego Perotti.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Mo Salah ni agbabọọlu to fakọyọ julọ lagbaye bayii'

'Ẹ dée ládé e ọba bọ́ọ̀lù'

Bi o tilẹ jẹ wi pe, llati inu ikọ Roma ni Salah ti ko ẹru rẹ wa si Liverpool, ṣugbọn ko fi eyi ṣe, pẹlu bo ṣe tan bii irawọ ọsan, ti n ba agba lẹru ni gbogbo asiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi waye.

Eleyi ti mu ki awọn eeyan kaakiri agbaye maa pe fun gbigbe ade ‘agbabọọlu to mọọ gba julọ lagbaye’ le Salah lori bayii.

'Mo Salah ni agbabọọlu to fakọyọ julọ lagbaye bayii'

'Mo Salah ti gbana jẹ'

'Mo Salah, Mo Salah, n da bi ẹdun'

'Mohammed Salah, ọlọwọ idan'

'Wo ohun tawọ̀n ololufẹ̀ Liverpool ṣe lẹ̀yin ti Salah fakọ̀yọ̀ loni'

'Ku iṣẹ Mohammed Salah'

Chamberlain da àwọn olólùfẹ́ Liverpool, ilẹ̀Gẹ̀ẹ́sì sí hílàhílo

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Alex Oxlade-Chamberlain ṣe fi ẹsẹ ṣeṣe ti wọn si gbee jade

Amọ ṣa o, nnkan kan ba ayọ aṣalẹ ọjọ iṣẹgun jẹ fun Liverpool.

Alex Oxlade-Chamberlain fi ẹsẹ rọ́

Ohun naa si ni pe, Alex Oxlade-Chamberlain fi ẹsẹ ṣeṣe, ti wọn si gbee jade.

Nibayii, ninu aibalẹ ọkan ni ọpọ awọn ololufẹ Liverpool wa bayii lori pe, ki ọrọ rẹ ma si di eyi ti ko ni lee gba bọọlu fun igba pipẹ, paapaa julọ bi idije ife ẹyẹ agbaye ṣe n bọ lọna.

Related Topics