Bayern Munich kò ní gbọ́; Real Madrid kò ní gbà lálẹ́ òní

Cristiano Ronaldo ti Real Madrid Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìdí iṣẹ́ ẹni latí ń mọni lọ́lẹ; Cristiano Ronaldo ti Real Madrid

Lálá yóò lù lálẹ́ òní, Ọjọ́rú nínú ìdíje UCL.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Robert Lewandowski lẹ́nu iṣẹ́ orí rán an

Ni'gbà tí ẹgbẹ́ agbábọ́òlù Bayern Munich àti Real Madrid yóò kojú ara wọn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kángun sí àṣekágbá ìdíje UCL tó ń lọ lọ́wọ́ ni Yúròòpù.

Bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ bọ́ọ̀lù kò ṣee fi ojú di.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Èrò onímọ̀ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀

Ogbeni Tijani Adewale ni: Kò sí ẹni tí kò lè lu ara wọn lálẹ́ òní nínú àwọn méjèèjì.

Ṣùgbọ́n, Ó ṣeéṣe kí Real Madrid fàgbàhan Bayern Munich nítorí pé wọ́n ti nà wọ́n nílé àti níta tẹ́lẹ̀.

Bákan náà ni wọn ti nà Bayern Munich ní ẹ̀ẹ̀maruǹ uń tí wọn pàdé sẹ́yìn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBayern Munich kò ní gbọ́; Real Madrid kò ní gbà lálẹ́ òní

Ìran ni oúnjẹ ojú, Ronaldo ati Lewandowski yóò wọ̀yá ìjà láìpẹ́