Gọngọ á sọ: Lewandowski yoo koju Cristiano Ronaldo lálẹ́ òní
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bayern Munich kò ní gbọ́; Real Madrid kò ní gbà lálẹ́ òní

Bayern Munich àti Real Madrid yóò kojú ara wọn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kángun sí àṣekágbá ìdíje UCL tó ń lọ lọ́wọ́ ni Yúròòpù.

Ìgbà kọkàndínlọ́gbọ̀n tí Real Madrid yóò yege dé ipele yìí ni.

Ìgbà kọkàndínlógún tí Bayern Munich yóò yege dé ipele yìí ni ti alẹ́ òní.