Lionel Messi gba àṣẹ àmì ìdánimọ̀ lágbàyé

Aworan Lionel Messi
Àkọlé àwòrán Ìlúmọ̀ọ̀ká agbábọ́ọ̀lù ni Lionel Messi jẹ́.

Ẹjọ́ ọdún méje parí, àmì ìdánimọ̀ Messi di òótọ́.

Lionel Messi, gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù àgbáyé, ti rí àṣẹ àmì ìdánimọ̀ gbà nílé ẹjọ́ EU General Court.

Agbábọ́ọ̀lù Barcelona àti Argentina náà ti wà lẹ́nu ẹjọ́ lílo orúkọ rẹ̀ sí ara àwọn ohun eèlò bíi aṣọ, bàtà, ọjà lóríṣíriṣii àti àwọn ohun eèlò eré ìdárayá tipẹ́tipẹ́.

Ilé iṣẹ́ olórúkọ ''Massi' ní Spain ló kọ́kọ́ ṣe lòdì sí ìyọ̀ǹda lílo orúkọ Messi tẹ́lẹ̀, pé, ó ṣeéṣe kí orúkọ máa dàpọ̀ lórí ohun eèlò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Messi ni gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù tó ń gbowó jùlọ làgbáyé.

O ń gba €126m (£108m) ni owó ọ̀yà rẹ̀ báyìí ní èyí tó ti ju €94m tí Cristiano Ronaldo ń gbà lọ.

Orúkọ Messi ti di oní àmì ìdánimọ̀ láti ìsìnyí lọ.

Àjànàkú nipò adarí rere, ó kúrò lẹ́rù ọmọdé

Fadá méji, ọmọ ìjọ 13 kú nínú ìkọlù darandaran

Ipò àgbà ló yẹ́ kí a ti bá olórí - Fani-Kayode