Aṣòfin Adeyẹmọ nífẹ̀ẹ́ sí ètò ìdájọ́ àti òfin

Aṣòfin Michael Adeyemọ Image copyright Facebook/Adeyemo
Àkọlé àwòrán Asòfin Michael Adeyemọ fẹ́ràn eré ìdárayá púpọ̀

Olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Òyọ́, Michael Adeyẹmọ tó dagbere fáyé lówúrọ̀ ọjọ́ ẹtì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Òkè Àdó, Ìbàdàn.

Olóògbé Adeyẹmọ tẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé girama ti ìjọ sẹ̀lẹ́ Òkè Àdó, Ìbàdàn.

Image copyright Facebook/Adeyemo
Àkọlé àwòrán Olóògbé Adésínà Adéyemo jẹ́ ẹni tó gbé àṣà Yorùbá lárugẹ

Olóògbé náà lọ sí fásítì ti ìlú Port Harcourt níbi t'óti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìdarí ètò ẹ̀kọ́ tí ó sì pegedé níbẹ̀.

Ògbẹ́ni Michael Adeyẹmọ nífẹ̀ẹ́ sí ètò ìdájọ́ àti òfin.

Eléyìí lọ́ jẹ́ kó lọ k'ẹ̀kọ́ láti di agbẹjọ́rò nìgbàtí ó gb'oyè amòfin ní fásítì ìlú Ibadan.

Image copyright Facebook/Adeyemo
Àkọlé àwòrán Ó pegedé láti di agbẹjọ́rò ni ọdún 2004, ó sì ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ amòfin Olujinmi àti Akeredolu
Image copyright Facebook/Adeyemo
Àkọlé àwòrán Aṣòfin Michael Adeyemo níbi ìpàdé àwọn agbẹjọ́rò ní ìlú Abuja

Họ́nọ́rébù Adeyemo bẹ̀rẹ̀ òsèlú ni ọdún 2007.

Ó ti fi ìgbàkan rí jẹ́ igbákejì alámòótó ní ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Òyọ́ ní sáà ilé tó kọjá lọ.

Image copyright Facebook/Adeyemo
Àkọlé àwòrán Ògbẹ́ni Michael Adeyemo jẹ́ ẹnití ó nífẹ̀ẹ́ sí eré orí-ìtàgé nígbà ayé rẹ̀

Òun ni aṣòfin àkọ́kọ́ tí àwọn ará Ìlà-oòrùn Ibarapa tí ó ń sojú yóò kọ́kọ́ dìbò yàn lẹ́ẹ̀mejì.

Olóògbé Adeyemo fi ìyàwó àti àwọn ọmọ sílẹ̀ lọ.