Guru Maharaji : Aṣòfin Adéyẹmọ kì bá tí kú kání ó mọ mi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈmi kò leè kú láéláé

Gbajúgbajà aṣíwájú ẹ̀sìn ni, Sat Guru Maharaji ti sọ wípé òun kò lè kú nítorí òun kìí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀.

Guru Maharaji ṣàlàyé fún aṣojúkọ̀ròyìn BBC Yorùbá, Adédayọ̀ Òkédáre, pé àwọn tó gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ jáde pé òun ti kú kò mọ̀ pé iná tí a bá dá de igún, ẹyẹ míràn níí yáa ni."Inú mi dùn púpọ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìròyìn ikú mi nítorí ó ṣe àfihàn bí mo ti ṣe gbajúmọ̀ tó ni. Àwọn tó wà nídìí ìròyìn náà kò fẹ́ ìlọsíwájú mi ni."

Aṣíwájú ẹ̀sìn náà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn kan tó jáde láìpé yìí ni oun ko lee ku rara o nitoripe, gẹ́gẹ́bi o ṣe sọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ níí kú.

Lórí ikú olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tó kú ní ọjọ́ ẹtì, Guru Maraji ni aṣòfin Adéyẹmọ kì bá tí kú kání ó mọ òun ni.