Zidane: Ọjọ́ ọ̀la mi kò nìí se pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ UCL

Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikò Real Madrid Zinedine Zidane Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Real Madrid wàákò pẹ̀lú Bayern Munich nínú ìdíje Champions League.

Ikò Real Madrid yóò gbéna wojú Bayern Munich lálẹ́ ọjọ́ ìsẹ́gun, nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kángun sí aṣekágbá ìdíje Champions League.

Real Madrid j'áwé olúborí nínú ìpele àkọ́kọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà pẹ̀lú àmìn ayò méjì ṣ'ẹ́yọọ̀kan lọ́sẹ̀ tó kọjá.

Ẹ̀wẹ̀, akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ Real Madrid, Zinedine Zidane ti sọ pé, títẹ̀ síwájú òun pẹ̀lú ikọ̀ náà, kò nìí se pẹ̀lú pé kí òun gba ife ẹ̀yẹ Champions League.

Ikọ̀ Real Madrid ń gbìyànjú láti gba Champions League l'ẹ́ẹ́kẹ̀ta lẹ́yìn ìgbàtí wọn ti gbàá lẹ́mèejì léra wọn.

Sùgbọ́n akọ́nimọ̀ọ́gbá fun ikọ alátakò Bayern Munich, Jupp Heynckes ti sọ pé, àwọn yóò ṣe àtúnse aṣiṣe tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù se lọ́sẹ̀ tó kọjá.