Ìkọlù Afghanistan: Akọ̀ròyìn BBC àti èèyàn mẹ́jọ jáláìsí

Aworan Ahmad Shah
Àkọlé àwòrán BBC sọ wipe Shah jẹ akọroyin ti awọn eniyan buyi fun, nitori o gbajugbaja, o si mọ isẹ rẹ ni isẹ

Akọroyin BBC kan ni wọn ti pa ni ila oorun agbeegbe khost, ni orilẹ́ede Afghanistan lọjọ ti wọn se ikọlu to pa eniyan ogoji, ti akọroyin mesan si wa ninu wọn.

Akọroyin BBC naa to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn(29) , Ahmad Shah lo ti sisẹ fun ọdun kan pẹlu ile ise BBC Afghan Service, ki ikọlu naa to waye ni Ọjọ Aje, Osu Kẹrin, Ọdun 2019.

Ninu atẹjade kan, adari ile isẹ BBC to n bojuto eto iroyin kaakiri agbaye, BBC World Service, Jamie Angus sọ wipe, Shah jẹ akọroyin ti awọn eniyan buyi fun, nitori o gbajugbaja, o si mọ isẹ rẹ ni isẹ

Ọga agba ile isẹ naa ati awon osisẹ kẹdun pẹlu ẹbi, ara ati ọrẹ akọroyin to papoda naa, wọn si sọ wipe awọn yoo sa ipa wọn lati gbaruku ti awọn idile akọroyin naa lasiko yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adari ile isẹ ọlọpaa lẹkun Khost, Abudul Hanan sọ fun BBC Afghan wipe, ni se ni awọn agbebọn ti wọn ko mọ yinbọn pa Shah lori kẹkẹ rẹ, ko to di wipe wọn gbe lo si ile iwosan amọ ẹpa ko boro mọ.

Awọn ọlọpaa agbegbe naa sọ wipe, iwadiii n lọ lọwọ lori isekupani naa.

Ti a ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni wọn juwe orilẹede Afganistan gẹgẹbi orilẹede kẹta to buru ju lagbaye fun awọn akọroyin lati sisẹ wọn bii isẹ.