Ìpàdé Buhari àti Trump: Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀

Àworan Buhari ati Trump Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbà àkọ́kọ́ nì yìí tí àwọn ààrẹ méjéèjì yóò máa pàdé

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sepade papọ pẹlu Aarẹ Ilẹ Amerika , Donald Trump ni ile aarẹ ni Washington ( White House ) .

Aarẹ Buhari ni aarẹ akọkọ ti aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump yoo gbalejo rẹ lati iha isalẹ asalẹ Sahara ni ilẹ Afirika.

Nigbati awọn adari mejeeji n ba awọn akọroyin sọrọ, Aarẹ Trump sọ wipe ijọba oun setan lati sisẹ pọ pẹlu ijọba orilẹede Naijiria lati gbogun ti awọn agbesunmọmi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn adari mejeeji fi ipinnu wọn han lati gbogun ti iwa ipa lagbaye

Awọn ohun ti wọn jiroro ni ọrọ eeto aabo, gbigbe ogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, idokowo laarin orilẹede mejeeji ati ẹtọ ọmọ eniyan.

Ababọ ipade Aarẹ Buhari ati Aarẹ Trump

  • Rira ọkọ okurufu mejila: Awọn adari mejeeji fi ipinnu wọn han lati gbogun ti iwa ipa lagbaye. Aarẹ Donald Trump sọ wipe Naijiria ti ra ọkọ ofurufu mejila lọwọ Amẹrika lati lee mu eto aabo gbooro lorilẹede Niajiria.
  • Eto aabo nipa Boko Haram: Aarẹ Buhari dupe lọwọ Aarẹ Trump fun iranlọwọ awọn ologun ilẹ Amẹrika, to kopa ninu kikọ awọn oloogun orilẹede Naijiria lọna ti wọn yoo gba fi sẹgun ikọ ẹsin o kọku Boko Haram: Awọn adari mejeeji sọ wipe opin yoo deba gbogbo ikọlu Boko Haram laipẹ.
  • Gbigbe ogun ti iwa ibajẹ: Aarẹ Donald Trump ni, ijọba Aarẹ Buhari se gudugudu meje ati yaya mefa lati gbogun ti iwa ibajẹ to wọpọ laarin awọn ọmọ Naijiria, ati wipe, awọn ti setan lati ran ijọba Naijiria lọwọ lati gbogun ti iwa ibajẹ ni gbogbo ọna.
  • Idokowo: Aarẹ Donald Trump ti gba Aarẹ Buhari niyanju lati mu idẹrun ba idokowo laarin orilẹede Naijiria ati ilẹ Amẹrika. Aarẹ Trump ni oun idunnu ni yoo jẹ fun oun, ti awọn ba lee maa ta ohun ọgbin ilẹ Amẹrika fun Naijira lati mu ibugbooro ba ọrọ aje orilẹede Naijiria.
  • Ẹtọ ọmọ eniyan ni Benue; Aarẹ Donald Trump ti sọ wipe opin gbọdọ de ba asa pipa awọn ọmọlẹyin Kristi kaakiri orilẹede Naijiria. O wa fi da awọn eniyan loju wipe, Amẹrika ko ni faye gba ija ẹsin lorilẹede Naijiria, ti opin yoo si de ba isekupani awọn Fulani Darandaran ni Benue.

Amọ, ọpọ eniyan ni ero wipe, ọrọ Aarẹ Donald Trump nipa isekupani awọn Kristeni lorilẹede Naijira lee mu ki ija ẹlẹsinjẹsin gbilẹ si.