Ìdíje Snooker: Hawkins fàgbà han Junhui

Barry Hawkins Image copyright @Barryhawkins
Àkọlé àwòrán Ìrírí kọjá abewú ni ọ̀rọ̀ ìdíje Snooker

Barry Hawkins sún síwájú nínú ìdíje tó kángun sí àṣekágbá àgbáyé fún eré Snooker tó n lọ lọ́wọ́.

Barry Hawkins tó jẹ́ ẹnìkẹfà tò mọ Snooker gbá jùlọ ni àgbáyé, ti kóná si ìdí Ding Junhui tó jẹ́ alámì-ẹ̀yẹ àgbáyé.

Barry na Ding pẹ̀lú àmi ayò mẹ́tàlá sí márùn ún nínú ìdíje náà.

Àwọn míràn ti wón yòó pàdé ni Judd Trump àti John Higgings ti Scortland, Kyren Wilson àti Mark Allen ti Nothern Ireland nígbà tí Carter yóò kojú Williams.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: