Yaya Toure yóò kúrò nínú ikọ̀ Man City lópin sàá yìí

Yaya Toure Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbà mẹ́rìndínlógún ni Yaya Toure ti ṣojú Man City ní sàá yìí.

Ògbóntagì agbábọ́ọ̀lù, tó tún jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ivory Coast, Yaya Toure, yóò kúrò nínú ikọ̀ Manchester City lópin sàá yìí.

Agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún tó kẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n yòó farahàn fún ìgbà ìkẹyìn l'Ọ́jọ́rú tó m bọ̀, lásìkò tí ikọ̀ rẹ̀ bá kojú Brighton.

Akọ́nimọ̀ọ́gbá rẹ̀, Pep Guardiola ló sọ bẹ́ẹ̀.

Toure, tó darapọ̀ mọ́ Man City láti Barcelona fún owó tó tó mílíọ́nù mẹ́rìnlélógún pọ́nhùn, tọ́wọ́ bọ ìwé àdéhùn ọdún kan nínú oṣù Kẹfà, 2017.

Guardiola ní, "Yaya darapọ̀ mọ́ wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìrìnàjò nàá''.

Àti pé "A ó fun un ní ohun tó tọ́ si i lásìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú Brighton, ìsìn ìdágbére tó bu iyì kún agbábọ́ọ̀lù.

Gbogbo àfojúsùn wa yóò dá lórí à ti borí fún Yaya, a ó gbìyànjú láti ṣé e fun."

Ọjọ́ kẹsàn án, oṣù Karùn ún, ni Man City yóò gbàlejò Brighton, kó tó ò rìnrìnàjò lọ sí Southampton fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kẹ́yìn ní sàá yìí.

Nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lé nigba ni Toure ti farahàn nínú ìdíje Premier League, fún sàá mẹ́jọ rẹ̀ ní pápá ìṣeré Etihad.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: