Marylove, ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ agbábọ́ọ̀lù orí pákó gbógo Nàìjíríà yọ

Marylove to gbe ife ẹyẹ dani Image copyright @marylovedwardtwitter
Àkọlé àwòrán Marylove ń digi àràbà lágbàyé

Ọmọ ọdún mẹ́tàlá di àjítannáwò lágbàyé

Marylove Edwards jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó ń gbèrò láti ṣe ju Serena Williams lọ́jọ́ ọ̀la lágbàyé.

ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ agbábọ́ọ̀lù orí pákó tó ń gbógo Nàìjíríà yọ lọ́wọ́lọ́wọ́ naa bá Ilé iṣẹ́ BBC Sport Africa sọ̀rọ̀ lórí àfojúsùn rẹ̀ fún ọjọ́ ọla pé yóò dùn púpọ̀.

Marylove ti gba àmì ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi bíi ti USTA Celsius Level 6 fawọn obinrin nilẹ̀ America nibi ti ó ti fàgbàhan àwón èèkàn agbábọ́ọ̀lù orí pákó bii Nina Sidhu, Anastasia Pestereva, Nicole Ciemark àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Opọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n ń pe Marylove ní orúkọ ìnagijẹ 'Serena Nàìjíríà'.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: