Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí Alex Ferguson kú lásìkò yìí

Sir Alex Ferguson Image copyright @alexfergusontwitter
Àkọlé àwòrán Ìlera lọ̀rọ̀, kò sẹ́ni tó fẹ́ kú

Lálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta tó kọjá ni Alex Ferguson, akọ́nimọ̀ọ́gbá fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United Tẹ́lẹ̀ ṣe iṣẹ́ abẹ.

Gbajúgbajà akọ́nimọ̀ọ́gbá fún Manchester United tẹ́lẹ̀ ń gba ìtọ́jú kíkún bayii nílé ìwòsàn Salford Royal Hospital lẹ́yìn ti wọn ṣe iṣẹ́ abẹ ninu ọpọlọ rẹ̀.

Ferguson ṣiṣẹ́ fún Manchester United láti ọdùn 1986 sí ọdún 2013.

Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n ń gbàdúrà fún ìléra pípé fún Ferguson bíí ohùn àwọn olólùfẹ́ Sporf tí wọn ni, ọ̀tọ̀ ni aàyè bọ́ọ̀lù pé:

Bákan náà ni àwọn FC Internazionale Milano sọ̀rọ̀ lójú òpó twitter wọn pé àwọn ń gbàdúrà fún ìlera Ferguson ní kíákíá

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn fún àdúrótì wọn fún Ferguson.

Brian kidd ṣàpèjúwe Ferguson gẹ́gẹ́ bíi èèkàn nínú bọ́ọ̀lù àgbáyé tó ń fa àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ sókè.

Fenerbahce ninu ìkànnì twitter rẹ̀ ni àwọn ń gbàdúrà fún ìlera pípé Ferguson.

Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n ṣapejuwe Ferguson ni ẹni tó ni ọgbọ́n àti sùúrù tó fi ń fa àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ sókè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: