Serena Williams: Mo fẹ́ àkókò si láti díje lorí amọ̀

Serena Williams Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gbajúgbajà ife ẹ̀yẹ mẹtalelogun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Serena Williams ti gba ninu ìdíje tẹniisi lágbáyé.

Serena Williams ti yọwọ ninu idije Italian Open ti yoo waye ninu osu yii ni ilu Rome.

Agba ọjẹ elere idaraya tẹniisi sọ eleyi di mimọ, lẹyin ọjọ marun un ti aìsàn ibà yọwọ́ rẹ láwo ìdíje Madrid Open.

Igbesẹ yii ti jẹ ki ọpọlọpọ maa ro pe Serena tun lee ma kopa ninu idije French Open ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn osu yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Serena ti gba ife ẹyẹ Italian Open nigba mẹrin ọtọọtọ.

Serena ti sọ tẹlẹ l'ọjọbọ ọṣẹ to kọja wipe, oun nilo akoko diẹ si ki oun to le ṣetan fun idije tẹniisi ori amọ.

Image copyright Twitter/Serena Williams
Àkọlé àwòrán Serena ti jáwé olúborí lẹ́ẹ̀rìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ́ nínú ìdíje Italian Open

Ní oṣù kẹta ni Serena pada sori papa, ni idije tẹniisi to wáyé ni Indian Wells ati Miami, léyìn tó bímọ.

Gbajúgbajà ife ẹ̀yẹ mẹtalelogun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Serena Williams ti gba, ninu ìdíje tẹniisi lágbáyé.

Related Topics