Yaya Toure: Èmi kò tíì féyìntì lẹnu iṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá

Yaya Toure Image copyright @barclaysLeague
Àkọlé àwòrán Yaya Toure tayọ̀ nínù àwọn agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Adulawọ

Agbábọ́ọ̀lù àárín láti Ivory Coast, Yaya Toure, ń dágbére fún Manchester lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ.

Gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù àárín fún Man City naa kópa nínú ìdíje to gbá gbẹ̀yìn fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ lọjọru.

Agbábọ́ọ̀lù àárín, ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ọhun sọ pe, òun ko tii mọ ibi ti orì ń gbé òun lọ ṣugbọn kìí ṣe China tabi agbegbe Middle East rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City fún Yaya Toure ni aṣọ ìrántí àti ìwé ìwolé wá wo ìdíje Man City títí ayé rẹ̀, gẹ́gẹ́ bi ẹ̀bùn o káre fún iṣẹ́ to ti ṣe fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà.

Toure ni òun kò tíì féyìntì lẹnu iṣẹ́ bọ́ọ̀lù

Eẹmẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Toure ti gbàmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Adulawọ to mọ̀ọ́ gbá jùlọ.

O ni òun kò tíì féyìntì lẹnu iṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá, pé òun kò kabamọ pé òun darapọ mọ Man City nigba náà.

Gbogbo àwọn ololufẹ rẹ̀ lo ń kíi.