Tani yóò lọ sí Champions League láàrin Chelsea ati Liverpool?

Jurgen Klopp ati Antonio Conte Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ìdíje Premier League parí fún sáà yìí

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liverpool ati Chelsea yoo gbiyanju lati yege fun idije UEFA Champions League gẹ́gẹ́ bí ìdíje Premier League ti parí fún saa yìí.

Ikọ Liverpool ati Chelsea yoo gbiyanju lati yege fun idije UEFA Champions League ni saa to n bọ.

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu ikọ Newcsatle ki wọn to le n'ireti lati yege.

Ṣugbọn ikọ Liverpool ni yoo pegede ti wọn ba le ta omin lasan nigbati wọn ba gbalejo Brighton ni papa iṣere Anfield.

Ẹwẹ, ọkan ninu ikọ Swansea tabi Southampton yoo fidi rẹmi lọ si idije championship loni.

Ikọ Southampton lo ni ireti lati duro ni Premier League pẹlu bi wọn ṣe n fi amin ayo meji saaju Swansea.

Gbogbo ifẹsẹwọnsẹ mẹwa to wa loni ni yoo waye lakoko kan naa