Salah ló fakọyọ jùlọ ní ìdíje Premier League fún saa yìí

Ẹlẹ́sẹ̀ ayò Mohamed Salah Image copyright Premier League
Àkọlé àwòrán Mohamed Salah fakọyọ fún ikò Liverpool ní sáà yìí lẹ́yìn ìgbà tó gbá àmìn ayò mẹ́tàlélógójì s'áwọ̀n

Ẹlẹsẹ ayo ikọ Liverpool Mohamed Salah tun ti gbara da lẹyin gba to tun gba ami ẹyẹ fun agbabọọlu to pegede julọ ni idije Premier League fun saa yii.

Aarọ Ọjọ Aiku ni ajọ to n ri si idije Premier League kede pe Salah lo yẹ julọ fun amin ẹyẹ naa.

Salah, ti o ti gba ami ẹyẹ PFA ati t'awọn akọroyin ere bọọlu afẹsẹgba tẹlẹ, lo n'ibo to pọju lọ ninu awọn marun ti wọn yan fun amin ẹyẹ naa.

Agbabọọlu fun Manchester City Kevin De Bruyne lo ṣe ipo keji ti goli Manchester United David de Gea si ṣe ipo kẹta.

Salah ti gba ami ayo mọkanlelọgbọn s'awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtaldinlogoji to ti gba ninu idije Premier League ni saa yi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Salah ni ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kejì tí yóò gba àmì ẹ̀yẹ PFA, lẹ́yìn Riyad Mahrez

Agbabọọlu naa to jẹ ọmọ bibi orilẹede Egypt ti gba amin ayo mẹtalelogoji s'awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ aadọta to ti gba fun ikọ Liverpool ni saa yìí.