Arsenal fún Wenger ní ẹ̀bùn àmúrelé tó jọjú

Wenger n wọ papa iṣire Huddersfield laarin ọpọ atẹwọ ati ẹyẹ Image copyright @Arsenal
Àkọlé àwòrán Kò sí ẹni tó mọ ibi tí ìrìnàjò yóò dojúkọ fún Arsene Wenger

Arsenal Wenger, olukọni Arsenal to n fipo silẹ ti gba ẹbun amurele manigbagbe lọwọ awọn agbabọọlu rẹ.

Ami ayo kan si odo ni Arsenal fi ṣe agba Huddersfield nibi aṣekagba ifẹsẹwọnsẹ fun saa liigi ilẹ Gẹẹsi fun ọdun 2017/2018.

Wenger ni inu ooun bajẹ gidigidi ati pe yoo nira lati gbe igbe aye ti ko ni ẹgbẹ Arsenal ninu.

Image copyright Arsenal
Àkọlé àwòrán Pierre-Emerick Aubameyang, agbọọlu ti Wenger ra kẹyin naa lo gba goolu to kẹyin, ni saa ikọni ati itọni Wenger ni Arsenal, wọle

Pierre-Emerick Aubameyang, agbọọlu ti Wenger ra kẹyin naa lo gba goolu to kẹyin, ni saa ikọni ati itọni Wenger ni Arsenal, wọle.

Eyi si ni igba akọkọ lọdun 2018 ti Arsenal yoo bori ninu Ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba nita ti kii ṣe ni ibuba wọn ni Emirate.

Odun mejila ni Wenger lo pẹlu Arsenal, ifẹsẹwọnsẹ to le ni ẹgbẹrun kan ati igba lo gba ti o si gba ife ẹyẹ liigi mẹta, FA meje nibẹ.

Ko tii si ẹni to mọ ibi ti irinajo yoo dojukọ fun gbajugbaja olukọni bọọlu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: